Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 19:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ọba Ẹṣkáyà gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ó sì lọ sí àgọ́ Olúwa

2. Ó sì rán Eliákímù olùtọ́jú ààfin, Ṣébínà akọ̀wé àti olórí àlùfáà gbogbo wọn sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, sí ọ̀dọ̀ wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì.

3. Wọ́n sì sọ fún ún pé, “Èyí ni ohun tí Héṣékáyà sọ: ọjọ́ òní yí jẹ́ ọjọ́ ìpọ́njú àti ìbáwí àti ẹ̀gàn, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ọmọdé wá sí ojú ìbímọ tí kò sì sí agbára láti fi bí wọn.

4. Ó lè jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yóò gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ olùdarí pápá, ẹni tí ọ̀gá rẹ̀, ọba Ásíríà, ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè sẹ̀sín, yóò sì báa wí fún ọ̀rọ̀ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún ìyókù àwọn tí ó wà láàyè.”

5. Nígbà tí ìránṣẹ́ ọba Héṣékáyà lọ sí ọ̀dọ̀ Àìṣáyà,

6. Àìṣáyà wí fún wọn pé, “Sọ fún ọ̀gá rẹ, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa sọ pé: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́—àwọn ọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ pẹ̀lú èyí ti ọba Áṣíríà ti sọ̀rọ̀ òdì sí mi.

7. Gbọ́! Èmi yóò rán ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ nígbà tí ó bá sì gbọ́ ariwo, yóò sì padà sí ìlú rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi yóò sì gbé gée lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”

8. Nígbà tí olùdarí pápá gbọ́ wí pé ọba Áṣíríà ti kúrò lákìsì ó sì padà ó sì rí ọba níbi ti ó gbé ń bá Líbíńà jà.

9. Nísinsìn yìí Ṣenakéríbù sì gbọ́ ìròyìn wí pé Tíránákà, ọba Etiópíà ti Éjíbítì wá ó sì ń yan jáde lọ láti lọ bá a jagun. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tún rán onísẹ́ sí Héṣékíáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí pé:

10. “Sọ fún Héṣékíáyà ọba Júdà pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí o gbékalẹ̀ kí ó tàn ó jẹ nígbà tí ó wí pé, ‘Jérúsálẹ́mù a kò ní fi lé ọwọ́ ọba Ásíríà.’

Ka pipe ipin 2 Ọba 19