Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 15:20-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ménáhémù fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Áṣíríà. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Áṣíríà padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́.

21. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ménáhémù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé ọba Ísírẹ́lì?

22. Ménáhémù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Pékáhíà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

23. Ní ọdún kẹẹ̀dógún Ásáríyà ọba Júdà, Pékáhíà ọmọ Ménáhémù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún ọdún méjì.

24. Pékáhíà ṣe búburú lójú Olúwa. Kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá.

25. Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Pékà ọmọ Remalíà, dìtẹ̀ síi. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gílíádì pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pékáhíà pẹ̀lú Árígóbù àti Áríè ní Kítadélì ti ààfin ọba ní Ṣamáríà. Bẹ́ẹ̀ ni Pékà pa Pékáhíà, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

26. Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Pékáhíà, gbogbo ohun tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì

27. Ní ọdún kejìléláàdọ́ta Ásáríyà ọba Júdà, Pékà ọmọ Rèmálíà di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà. Ó sì jọba fún ogún ọdún.

Ka pipe ipin 2 Ọba 15