Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 15:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà náà Ménáhémù ọmọ Gádì lọ láti Tírísà sí Ṣamáríà. Ó dojúkọ Ṣalúmù ọmọ Jábésì ní Samáríà, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

15. Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣalúmù, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.

16. Ní ìgbà tí Ménáhémù ń jáde bọ̀ láti Tíríṣà, ó dojúkọ Tífíṣà àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, Nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè. Ó yọ Tífsà kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún.

17. Ní ọdún kọkàndínlógójì ti Ásáríyà ọba Júdà, Ménáhémù ọmọ Gádì di ọba Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní Samáríà fún ọdún mẹ́wàá.

18. Ó ṣe búburú lójú Olúwa, ní gbogbo ìjọba rẹ̀. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá.

19. Nígbà náà, Púlù ọba Ásíríà, gbógun ti ilẹ̀ náà, Ménáhémù sì fún un ní ẹgbẹ̀rin talẹ́ńtì fàdákà láti fi gba àtìlẹyìn rẹ̀ àti láti fún ìdúró tirẹ̀ lágbára lórí ìjọba.

20. Ménáhémù fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Áṣíríà. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Áṣíríà padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́.

Ka pipe ipin 2 Ọba 15