Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 14:23-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ní ọdún kẹẹ̀dógún tí Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà, Jéróbóámù ọmọ Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì di ọba ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún ọ̀kànlélógójì ọdún.

24. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì. Èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá.

25. Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Ísírẹ́lì padà láti Lebo-Hámátì sí òkú aginjù. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jónà ọmọ Ámítaì, wòlíì láti Gátì Héférì.

26. Olúwa ti rí bí olúkúlùkù yálà ẹrú tàbí òmìnira, ti ń jìyà gidigidi; kò sì sí ẹnìkan tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

27. Láti ìgbà tí Olúwa kò ti wí pé òhun yóò bu àbùkù lu orúkọ Ísírẹ́lì láti abẹ́ ọ̀run. Ó gbà wọ́n là, lọ́wọ́ Jéróbóámù ọmọ Jéhóásì.

28. Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jéróbóámù, gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo àwọn àṣeyọrí ológun rẹ̀ àti bí ó ṣe gbà padà fún Ísírẹ́lì lápapọ̀. Dámásíkù àti Hámátì, tí ó ti jẹ́ ní Yáúdì, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

29. Jéróbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àwọn ọba Ísírẹ́lì Ṣekaríyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ka pipe ipin 2 Ọba 14