Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 11:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Ataláyàyà ìyá Áhásáyà rí i wí pé ọmọ rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀ṣíwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba náà run.

2. Ṣùgbọ́n Jéhóṣébà ọmọbìnrin ọba Jéhórámù àti arábìnrin Áhásáyà, mú Jóásì ọmọ Áhásáyà, ó sì jí i lọ kúrò láàárin àwọn ọmọ aládé bìnrin ti ọba náà, tí ó kù díẹ̀ kí a pa. Ó gbé òhun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù láti fi pamọ́ kúrò fún Ataláyà; Bẹ́ẹ̀ ni a kò pa á.

3. Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú olùtọ́jú ní ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataláyà fi jọba lórí ilẹ̀ náà.

4. Ní ọdún kéje, Jéhóíádà ránṣẹ́ sí àwọn olóórí ní ọrọrún àwọn balógun àti àwọn olùṣọ́, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Ó ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, ó sì fi wọ́n sí abẹ́ ìbúra nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Níbẹ̀ ni ó fi ọmọkùnrin ọba hàn wọ́n.

5. Ó pàṣẹ fún wọn, wí pé, “Ìwọ tí ó wà nínú àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ta tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi—ìdámẹ́ta yín fún síṣọ́ ààfin ọba.

6. Ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn Ṣúrì, àti ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ẹ̀yìn olùṣọ́, tí ó yípadà ní síṣọ́ ilé tí a kọ́,

7. Àti ẹ̀yin tí ó wà ní ẹgbẹ́ kejì yóòkù tí kì í lọ ibi iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi gbogbo ni kí ó ṣọ́ ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọba.

8. Ẹ mú ibùjókòó yín yí ọba ká, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ọgbà yìí gbúdọ̀ kú. Ẹ dúró súnmọ́ ọba ní ibikíbi tí ó bá lọ.”

9. Olórí àwọn ọrọọrún ṣe gẹ́gẹ́ bí Jéhóíádà àlùfáà ti paà láṣẹ́. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ àwọn tí ó ń lọ sí iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jéhóíádà àlùfáà.

10. Nígbà náà, ó fún àwọn olórí ní àwọn ọ̀kọ̀ àti àwọn apata tí ó ti jẹ́ ti ọba Dáfídì tí ó sì wà nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

Ka pipe ipin 2 Ọba 11