Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 9:3-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà tí ayaba Ṣébà rí ọgbọ́n Sólómónì àti pẹ̀lu ilé tí ó ti kọ́,

4. Oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjòkòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ ọrẹ sísun tí ó ṣe ní ilé Olúwa, ó sì ní ìdálágara.

5. Ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ, òtítọ́ ni.

6. Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi. Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdàjọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi: ìwọ ti tàn kọ já òkìkí tí mo gbọ́.

7. Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwó nínú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ!

8. Ìyìn lóyẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Ísírẹ́lì láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.”

9. Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà talẹ́ntì wúrà (120). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tíì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣébà fifún ọba Sólómónì.

10. Àwọn ènìyàn Húrámù àti àwọn ọkùnrin Sólómónì gbé wúrà wá láti Ófírì, wọ́n sì tún gbé igi álígúmù pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá.

11. Ọba sì lo igi álígúmù náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun ọ̀nà orin fún àwọn akọrin. Kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti rírí ní ilẹ̀ Júdà.

12. Ọba Sólómónì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ohun tí ó bèèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀.

13. Ìwọ̀n wúrà tí Sólómónì gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà talẹ́ntì (666),

14. Láì tíì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Árábíà àti àwọn báálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Sólómonì.

15. Ọba Solómónì sì ṣe igba (200) àṣà wúrà lílù: ẹgbẹ̀ta (6,000) àsà tí a fi òlùlù wúrà sí òkànkàn sékélì.

16. Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) kékeré ṣékélì tí a fi òlù lù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (3,000) sékélì wúrà nínú àpáta kọ̀kan. Ọba sì kó wọn sínú ilé ti igbó Lébánónì.

17. Nígbà náà ọba sì ṣe ìtẹ́ pẹ̀lú èyín erin ńlá kan ó sì fi wúrà tó mọ́ bò ó.

18. Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpóti ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn. Ní ìhá méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìropá, pẹ̀lú kìnnìun tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 9