Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 9:10-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Àwọn ènìyàn Húrámù àti àwọn ọkùnrin Sólómónì gbé wúrà wá láti Ófírì, wọ́n sì tún gbé igi álígúmù pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá.

11. Ọba sì lo igi álígúmù náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun ọ̀nà orin fún àwọn akọrin. Kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti rírí ní ilẹ̀ Júdà.

12. Ọba Sólómónì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ohun tí ó bèèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀.

13. Ìwọ̀n wúrà tí Sólómónì gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà talẹ́ntì (666),

14. Láì tíì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Árábíà àti àwọn báálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Sólómonì.

15. Ọba Solómónì sì ṣe igba (200) àṣà wúrà lílù: ẹgbẹ̀ta (6,000) àsà tí a fi òlùlù wúrà sí òkànkàn sékélì.

16. Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) kékeré ṣékélì tí a fi òlù lù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (3,000) sékélì wúrà nínú àpáta kọ̀kan. Ọba sì kó wọn sínú ilé ti igbó Lébánónì.

17. Nígbà náà ọba sì ṣe ìtẹ́ pẹ̀lú èyín erin ńlá kan ó sì fi wúrà tó mọ́ bò ó.

18. Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpóti ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn. Ní ìhá méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìropá, pẹ̀lú kìnnìun tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn.

19. Kìnnìún méjìlá dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́ta, ọ̀kan àti ní ìhà olúkúlùkù àtẹ̀gùn kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti ṣe rí fún ìjọba mìíràn.

20. Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solómónì ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò agbo ilé ní ibi igbó Lébánonì ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì sí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì.

21. Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Húrámù ń bojútó. Ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin, àti ìnàkí àti ẹyẹ ológe wá.

22. Ọba Solómónì sì tóbi nínú ọlá ńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ.

23. Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojú rere lọ́dọ̀ Sólómónì láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 9