Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 7:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Àwọn àlùfáà wọn kò sì le wo ilé Olúwa náà nítorí pé ògo Olúwa kún un.

3. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo Olúwa lórí ilé Olúwa náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin Olúwa, wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa wí pé,“Nítorí tí ó dára;àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé.”

4. Nígbà náà ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn sì rú ẹbọ níwájú Olúwa.

5. Ọba Sólómónì sì rúbọ ọrẹ ti ẹgbà á mọ́kànlá (22,000), orí màlúù àti àgùntàn àti ọkẹ́ mẹ́fà àgùntàn àti ẹranko. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn ya ilé Ọlọ́run sí mímọ́.

6. Àwọn àlùfáà dúró ní àyè wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Léfì ti ṣe pẹ̀lú ohun èlò orin Olúwa, tí ọba Dáfídì ti ṣe fún ìyìn Olúwa àti tí á lò nígbà tí ó dúpẹ́, wí pé, “àànú rẹ̀ sì dúró láéláé,” níwájú àwọn ọmọ Léfì, àwọn àlùfáà sì fọn ipè, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dúró.

7. Sólómónì sì yà sọ́tọ̀ láàrin àgbàlá níwájú ilé Olúwa, níbẹ̀ sì ni ó ti se ìrúbọ ọrẹ sísun àti ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ó ti ṣe kò lè gba ọrẹ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọ̀rá náà.

8. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì se àsè ní àkókò náà fún ọjọ́ méje àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ àti ìjọ ènìyàn ńlá, àwọn ènìyàn láti Lébò Hámátì títí dé odò Éjíbítì.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 7