Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 4:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó se pẹpẹ idẹ, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá fún gíga.

2. Ó ṣe agbada dídà ńlá tí ó rí róbótó ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé etí èkejì ìgbọ̀nwọ́ márùn ún sì ni gíga rẹ̀.

3. Lábẹ́ etí, àwòrán àwọn akọ màlúù yíká mẹ́wàá sí ìgbọ̀nwọ́ kan. Àwọn akọ màlúù náà ni á dá ní ọ̀nà méjì ní àwòrán kan pẹ̀lú okùn.

4. Okùn náà dúró lóri akọ màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúsù mẹ́ta kọjú sí ìlà oòrùn. Òkun náà sì sinmi lórí wọn àti gbogbo ìhà ẹ̀yìn wọn sì wà ní apá àárin.

5. Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dà bí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dógun ìwẹ̀ dúró.

6. Ó ṣe pọnunpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúṣù àti márùn ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ọrẹ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo òkun fún fífọ nǹkan.

7. Ó ṣe ìgbe fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúsù àti márùn ún ní ìhà àríwá.

8. Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa, márùn un ní gúṣù àti márùn ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́rún ọpọ́n ìbùwọ̀n wúrà.

9. Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 4