Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 36:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ọba Éjíbítì lé e kúrò lórí ìtẹ́ ní Jérúsálẹ́mù ó sì bù fún un lórí Júdà, ọgọ́rún talẹ́ńtì fàdákà (100) àti talẹ́ntì wúrà kan.

4. Ọba Éjíbítì sì mú Élíákímù, arákùnrin Jehóáhásì, jẹ ọba lórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù, ó sì yí orúkọ Eliákímù padà sí Jéhóíákíámù, ṣùgbọ́n Nékò mú arákùnrin Eliákímù, Jehóáhásì ó sì gbé e lórí Éjíbítì.

5. Jéhóíákímù sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

6. Nebukadínésárì ọba Bábílónì sì mú un, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti mú-un lọ sí Bábílónì.

7. Nebukadínésárì pẹ̀lú mú-un lọ sí Bábílónì, ohun èlò láti ilé Olúwa, ó sì mú wọn lọ sí ààfin tirẹ̀ níbẹ̀.

8. Ìyòókù isẹ́ ìjọba Jéhóíákíámù, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti Júdà. Jéhóíákínì ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

9. Jehóiakínì sì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún (18) nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ́ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta àti ijọ́ mẹ́wàá ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa.

10. Ní àmọ́dún, ọba Nebukadínsárì ránsẹ́ síi ó sì mú-un wá sí Bábílónì, pẹ̀lú ohun èlò dáradára láti ilé Olúwa, ó sì mú arákùnrin Jehóíákínì, Sedekíà, jọba lórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

11. Sedekíáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlèlógún. Nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlá.

12. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ ko si rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremíà wòlíì, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ Olúwa.

13. Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadinésárì pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ẹni tí ọrùn rẹ̀ wàkì, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

14. Síwájú síi gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀ èdè wọ́n sì sọ ilé Olúwa di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 36