Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 34:20-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hílíkíyà, Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì, Ábídónì ọmọ Míkà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáíà ìránṣẹ́ ọ̀nà.

21. “Ẹ lọ kí ẹ lọ bérè lọ́wọ́ Olúwa fún mi fún àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti Júdà nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tíì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”

22. Híkíánì àti àwọn ènìyàn tí a yàn sì lọ láti sọ̀rọ̀ sí àwọn wòlíì Húlídà aya Ṣálúmù ọmọ Tókátì, ọmọ Hásíràh, olùtọ́jú ibi ìkásọsí, ó sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ní ìhà kejì.

23. Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé,

24. ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Júdà.

25. Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibíyìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 34