Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 34:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó sì ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa, ó sì rìn ọ̀nà baba rẹ̀ Dáfídì, kò sì yà sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí òsì.

3. Ní ọdún kẹ́jọ ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí íwá ojú Ọlọ́run Baba Dáfídì. Ní ọdún kéjìlá (12). Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wẹ Júdà àti Jérúsálẹ́mù mọ́ kúrò ní ibi gíga rẹ̀, ère òrìṣà, àti ère yíyá àti ère dídà.

4. Lábẹ́ àpẹẹrẹ àwọn pẹpẹ Bálímù ni a yí lulẹ̀, ó sì fọ́ àwọn ère sí wẹ́wẹ́, ó run àwọn pẹpẹ tí ó wà lórí rẹ̀, wọ́n sì fọ́ túútúú àti àwọn ère dídá, àwọn òrìṣà àti ère dídá. Èyí tí ó fọ́ wọn sì lùúlùú, ó sì gbọ̀n wọ́n sí orí ìsà òkú àti àwọn tí ó ń rúbọ sí wọn.

5. Ó sì sun àwọn egungun àwọn àlùfáà lórí pẹpẹ wọn, Bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wẹ Júdà àti Jrusálẹ́mù mọ́.

6. Ní ìlú Mánásè, Éfíráímù àti Síméónì, àní títí ó fi dé Náfítalì, àti nínú àwọn, ó tú ilé wọn yíkáyíká.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 34