Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 33:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mánásè jẹ́ ọmọ ọdún Méjìlá nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta.

2. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa. Nípa títẹ̀lé ọ̀nà iṣẹ́ ìríra ti àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn.

3. Ó tún kọ́ àwọn ibi gíga tí baba rẹ̀ Heṣekáyà ti fọ́ túútúú. Ó sì gbé àwọn pẹpẹ dìde fún àwọn Báálì ó sì ṣe àwọn òpó Áṣérà. Ó foríbalẹ̀ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run ó sì sìn wọ́n.

4. Ó kọ́ àwọn pẹpẹ sínú ilé Olúwa ní èyí tí Olúwa ti wí pé “Orúkọ mi yóò wà ní Jérúsálẹ́mù títí láé.”

5. Nínú ààfin méjèèje ti ilé Olúwa, ó kọ́ àwọn pẹpẹ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run

6. Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rúbọ nínú iná ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Bẹni-Hínómù, ó ń ṣe oṣó, àfọ̀ṣẹ, ìsàjẹ́ pẹ̀lú bíbéèrè lọ́dọ̀ àwọn abókúsọ̀rọ̀, àti ẹlẹ́mìí. O se ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.

7. Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dáfídì àti sí ọmọ rẹ̀ Solómónì, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jérúsálẹ́mù, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 33