Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 3:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìloro tí ó wà níwájú ilé Olúwa náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́.Ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú kìkì wúrà.

5. Ó fi igi fírì bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bòó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n.

6. Ó se ilé Olúwa náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Góòlù tí ó lò jẹ́ wúrà párifáímù.

7. Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa Pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri.

8. Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé Olúwa mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ọgọ́rin mẹ́fà talẹ́ntì ti wúrà dáradára.

9. Ìwọn àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta Ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà.

10. Ní ibi mímọ́ jùlọ, ógbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà.

11. Iye ìyẹ́ apá ìbú atẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa. Nígbà tí ìyẹ́ apa kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-un ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 3