Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 3:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Níwájú ilé Olúwa náà ó ṣe òpó méjì tí lápapọ̀ jẹ́ márùn ún dín lógójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, olúkúlùkù pẹ̀lú olórí lórí rẹ̀ tí o ń wọn ìgbọ̀nwọ́ márùn ún.

16. Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà. Ó ṣe ọgọ́rin Pomígíránátìo (orúkọ èso igi) ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà

17. Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé Olúwa, ọ̀kan sí gúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúsù, ó ṣe ní Jákínì àti èyí ti àríwá, ó ṣe ní Bóásì.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 3