18. Nígbà tí àwọn ará Fílístínì sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n nì àti síhà gúsù Júdà. Wọ́n sẹ́gun wọ́n sì gba Béti-ṣémésì, Áíjálónì àti Gédérótì, àti Sókò, Tímínà, a ri Gímísò, pẹ̀lú ìletò wọn.
19. Olúwa sì rẹ Júdà sílẹ̀ nítorí Áhásì ọba Ísírẹ́lì, nítorí ó sọ Júdà di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì se ìrékọjá gidigidi sí Olúwa.
20. Tílgátì-Pílésárì ọba Ásíríà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́.
21. Áhásì mú díẹ̀ nínú ìní ilé Olúwa àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Ásíríà: ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́.
22. Ní àkókò ìpọ́njú rẹ̀ ọba Áhásì sì di aláìsòótọ́ sí Olúwa.
23. Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Dámásíkù, ẹni tí ó sẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, “Nítorí àwọn òrìṣà àwọn síríà ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Ísírẹ́lì.
24. Áhásì sì kó jọ gbogbo ohun èlò lati ilé Olúwa jọ ó sì kó wọn lọ. Ó sì ti ilẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jérúsálẹ́mù.
25. Ní gbogbo ìlú Júdà ó sì kọ́ ibi gíga láti sun ẹbọ fún àwọn Ọlọ́run mìíràn. Kí ó sì mú Olúwa, Ọlọ́run àwọn Baba wọn bínú.