Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 27:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Jótanì sì kọ́ ẹnu ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Óféli.

4. Ó sì kọ́ àwọn ìlú ní Júdà òkè àti nínú igbó àti ilé ìsọ́, ó mọ ilé odi.

5. Jótanì sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ámónì ó sì borí wọn. Ní ọdún náà àwọn ará Ámórì wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì fàdákà àti ẹgbàaàrún òsùwọ̀n àlìkámà àti ẹgbàárún balì. Àwọn ará Ámónì gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta.

6. Jótamù sì di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà tótọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

7. Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jótamù, pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀ pẹ̀lú ohun mìíràn tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà.

8. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún.

9. Jótamù sì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Dáfídì, Áhásì ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 27