Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 26:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ní Jérúsálẹ́mù ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun tí ó ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ihumọ̀ ọlọgbọ́n ọkùnrin fún lílò lórí ilé-ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.

16. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ùsáyà jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìsòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wo ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.

17. Ásáríyà àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà Olúwa mìíràn sì tẹ̀lée.

18. Wọ́n sì takòó, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ùsáyà, láti sun tùràrí sí Olúwa. Èyi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Árónì, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìsòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run.”

19. Ùsía, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣe tán láti sun tùràrí, ó sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé Olúwa, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀.

20. Nígbà tí Ásáríyà olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì ríi wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lú pẹ̀lú, òun tìkálárarẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí Olúwa ti lùú.

21. Ọba Ùsíá sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé ọ̀tọ̀ adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ile Olúwa. Jótamù ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 26