Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 23:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kéje, Jehóádà fi agbára rẹ̀ hàn. O dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn alákòóso, ọrọrún kan, Ásáríyà ọmọ Jérohámù, Íṣímáẹ́lì ọmọ Jehóhánániì Ásáríyà ọmọ Óbédì, Máséyà ọmọ Ádáyà àti Élíṣáfátì ọmọ Ṣkírì.

2. Wọ́n lọ sí gbogbo Júdà, wọ́n sì pe àwọn ará Léfì àti àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn ará Ísírẹ́lì láti gbogbo àwọn ìlú jọ. Nígbà tí wọ́n wá sí Jérúsálẹ́mù.

3. Gbogbo ìpéjọ dá májẹ̀mú pẹ̀lú ọba ní ilé Ọlọ́run.Jéhóiádà wí fún wọn pé, “Ọmọkùnrin ọba yóò jọba, bí Olúwa ti ṣèlérí nípa àwọn àtẹ̀lé Dáfídì.

4. Nísinsinyìí èyí ni ohun tí ó yẹ kí ó ṣe: Ìdámẹ́ta àlùfáà yín àti àwọn ará Léfì tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi ni kí ó bojútó àwọn ìlẹ̀kùn.

5. Ìdámẹ́ta yín níbi ààfin ọba àti ìdámẹ́ta níbi ẹnu odi ìdásílẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí ó wà ní àgbàlá ààfin ilé Olúwa.

6. Kò sí ẹnìkan tí ó gbọdọ̀ wọ inú ilé Olúwa yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì tí a rán ní iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n lè wọlé nítori tí a ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí wọn ó ṣọ ohun tí Olúwa ti yàn fún wọn.

7. Àwọn ará Léfì gbọ́dọ̀ wà ní ìdúróṣinṣin yí ọba ká. Olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé Olúwa ni kí ẹ pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tí ó bá lọ.”

8. Àwọn ará Léfì àti gbogbo ọkùnrin Júdà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehóádà Àlùfáà ti palásẹ. Olukúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀, àwọn tí wọ́n lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n ń kúrò ní ibi iṣẹ́. Nítorí Jéhóiádà àlùfáà kò ì tí tú ìpín kankan sílẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 23