Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 21:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Lẹ́yìn gbogbo èyí, Olúwa jẹ Jéhórámù níyà pẹ̀lú àrùn tí kò ṣeé wò sàn ti ìfun.

19. Ní àkókò kan ní ìparí ọdún kejì, àwọn ìfun rẹ̀ jáde nítorí àrùn náà ó sì kú nínu ìrora ńlá. Àwọn Ènìyàn rẹ̀ kò dá iná láti fi bọlá fún un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba a rẹ̀.

20. Jéhórámù jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ní ìgbà tí ó di ọba, Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́jọ. Ó kọjá lọ, kò sí ẹni tí ó kábàámọ̀. A sì sin ín si ìlú ńlá ti Dáfídì. Ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ibojì àwọn ọba.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 21