Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 21:13-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì, ìwọ sì ti tọ́ Júdà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe. Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé bàbá à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ.

14. Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìn yìí, Ọlọ́run ti fẹ́rẹ́ lu àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn ńlá.

15. Ìwọ tìkalára yóò ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú Àìsàn lílọ́ra ti ìfun, títí tí àìsàn náà yóò fi jẹ́ kí àwọn ìfun rẹ jáde sí ìta.’ ”

16. Olúwa ru ìbínú àwọn, ará Fílístínì àti àwọn Árábù tí wọ́n ń gbé ní Ẹ̀bá àwọn ará Kúsì.

17. Wọ́n dojú ìjà kọ Júdà, wọ́n gbàá, wọ́n sì kó gbogbo ọrọ̀ tí a rí ní ilé ọba pẹ̀lú, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin kankan kò kù sílẹ̀ fún un bí kò ṣe Áhásáyà, tí ó kéré jùlọ.

18. Lẹ́yìn gbogbo èyí, Olúwa jẹ Jéhórámù níyà pẹ̀lú àrùn tí kò ṣeé wò sàn ti ìfun.

19. Ní àkókò kan ní ìparí ọdún kejì, àwọn ìfun rẹ̀ jáde nítorí àrùn náà ó sì kú nínu ìrora ńlá. Àwọn Ènìyàn rẹ̀ kò dá iná láti fi bọlá fún un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba a rẹ̀.

20. Jéhórámù jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ní ìgbà tí ó di ọba, Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́jọ. Ó kọjá lọ, kò sí ẹni tí ó kábàámọ̀. A sì sin ín si ìlú ńlá ti Dáfídì. Ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ibojì àwọn ọba.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 21