Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 2:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Hírámù ọba Tírè fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Sólómónì:“Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti se ọ́ ní ọba wọn.”

12. Hírámì fi kún un pe:“Ìyìn ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó dá ọ̀run òun ayé! O ti fún ọba Dáfídì ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó kún fún ìmọ̀ àti àkíyèsí, tí yóò kọ́ ilé fún Olúwa àti ààfin fún ara rẹ̀.

13. “Èmi ń rán Húrámì-Abi, sí ọ ọkùnrin tí ó kún fún ìmọ̀ ńlá,

14. Ẹni tí ìyá rẹ̀ wá láti Dánì àti tí Baba a rẹ̀ wá láti Tírè. A kọ́ ọ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti igi, àti pẹ̀lú àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ ọ̀run àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó dára. Ó ní ìmọ̀ nínú gbogbo oríṣìí iṣẹ́ fínfín. Ó sì le ṣe àwárí irú ẹ̀yà kẹ́yà tí a bá fún un. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn oníṣọ̀nà pẹ̀lú àwọn ènìyàn Olúwa mi, Dáfídì baba a rẹ.

15. “Nísinsin yìí, jẹ́ kí Olúwa mi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àlìkámọ̀ àti bálì àti òróró Ólífì náà àti ọtí tí ó ti ṣe ìlérí.

16. Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lébanónì tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Jópà. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù.”

17. Sólómónì ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Ísírẹ́lì lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dáfídì ti ṣe; a sì ka iye wọn sí (153,600) ọ̀kẹ́mẹ́jọ ó dín egbéjì-lélọ́gbọ̀n.

18. Ó sì yan ẹgbàá márùndínlógójì nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbéjìdínlógún alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 2