Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 18:17-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ọba Ísírẹ́lì wí fún Jéhóṣáfátì pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?”

18. Mikáyà tẹ̀ṣíwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa: Mo rí Olúwa jòkó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì.

19. Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Áhábù ọba Ísírẹ́lì lọ sí Rámátì Giléádì kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’“Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún.

20. Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá ṣíwájú, ó dúró níwájú Olúwa ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’“ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ Olúwa beèrè.

21. “ ‘Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì.’ Ó wí pé.“ ‘Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí,’ ni Olúwa wí. ‘Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’

22. “Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìn yìí Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ. Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ.”

23. Nígbà náà Sedékíà ọmọ Kénánà lọ sókè ó sì gbá Míkáyà ní ojú. “Ní ọ̀nà wo níi ẹ̀mí Olúwa gbà kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?” Ó sì bèèrè.

24. Míkáyà sì dáhùn pé, “ìwọ yóò ṣe ìwadìí ní ọjọ́ tí ìwọ yóò sápamọ́ sínú ìyẹ̀wù.”

25. Ọba Ísírẹ́lì paálásẹ pé, “Mú Mikáyà kí o sì ran padà sí Ámónì olóri ìlú àti sí Jóáṣì ọmọ ọba,

26. Ó sì wí pé ‘Èyí ni ohun tí ọba sọ: ẹ fi ènìyàn yìí sínú túbú kí ẹ má sì ṣe fún-un ní ohunkóhun ṣùgbọ́n àkàrà àti omi títí tí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà.’ ”

27. Míkáyà sì wí pe, “Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, Olúwa kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà náà, ó sì fi kún-un pé, “Ẹgbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn!”

28. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jéhóṣáfátì ọba Júdà lọ sókè ní Rámótì Gílíádì.

29. Ọba Ísírẹ́lì sọ fún Jéhóṣáfátì pé, “Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgunwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 18