Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 17:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Lára àwọn ará Fílístínì, mú ẹ̀bùn fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó ọba wá fún Jéhóṣáfátì, àwọn ará Árábíà sì mú ọ̀wọ́ ẹran wá fún-un, ẹgbàrin ó dín ọ̀dúnrún àgbò àti ẹgbarìndín ní ọ̀ọ́dúnrún òbúkọ.

12. Jéhóṣáfátì sì ń di alágbára nínú agbára síi, ó sì kọ́ ilé olódi àti ilé ìsúra púpọ̀ ní Júdà

13. Ó sì ní ìṣúra ní ìlu Júdà. Ó sì tún ní àwọn alágbára jagunjagun akọni ọkùnrin ní Jérúsálẹ́mù.

14. Iye wọn gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn nì wọ̀nyí:Láti Júdà, àwọn olórí ìsùkan ti ẹgbẹ̀rún (1,000):Ádínà olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dó gún alágbára akọni ọkùrin (300, 00);

15. Èkejì Jéhósáfátì olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá ọkùnrin (280,000);

16. Àtẹ̀lé Ámásíà ọmọ Síkírì, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000).

17. Láti ọ̀dọ̀ Bẹ́ńjámínì:Élíádà, alágbára akọni ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin pẹ̀lú ọrun àti àpáta ìhámọ́ra;

18. Àtẹ̀lé Jéhósábádì, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án (180,000) jagunjagun ọkùnrin múra sílẹ̀ fún ogun.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 17