Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 16:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ní àkókò náà wòlíì Hánánì wá sí ọ̀dọ̀ Ásà ọba Júdà, ó sì wí fún un pé, “nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé ọba Árámù, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Árámù ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ.

8. Àwa kì í ṣe ará Etiópíà àti àwọn ará Líbíà àwọn alágbára ogun pẹ̀lu ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ.

9. Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”

10. Ásà sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Ásà sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.

11. Àwọn iṣẹ́ ìjọba Ásà, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Júdà àti Ísírẹ́lì.

12. Ní ọdún kọkàndínlógójì (39) ìjọba rẹ̀, Ásà sì ṣe àìsàn pẹ̀lú àrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Lákókò àrùn rẹ̀ ó múná, kó dà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan.

13. Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Ásà kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀,

14. Wọ́n sì sin ín sínú ìsà òkú tí ó ti gbé jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dáfídì. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dìdùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n àwọn alápòlù pèsè, wọ́n sì ṣe ìjóná ńlá nínú ọlá ńlá rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 16