2 Kíróníkà 16:14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Wọ́n sì sin ín sínú ìsà òkú tí ó ti gbé jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dáfídì. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dìdùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n àwọn alápòlù pèsè, wọ́n sì ṣe ìjóná ńlá nínú ọlá ńlá rẹ̀.