Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 15:13-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Olúwa Ọlọ́run Isirẹ́lì, pípa ni á ó paá láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin.

14. Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún Olúwa àti pẹ̀lú ìhó nla àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè.

15. Gbogbo Júdà yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri

16. Ọba Ásà rọ ìyá ńlá rẹ̀ Mákà lóyè láti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyá ọba nítorí tí ó ti ṣe òpó Áṣérà tí ń lé ni sá. Ásà gé òpó náà lulẹ̀, wòó, ó sì jóo ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì.

17. Ṣùgbọ́n a kò mú àwọn ibi gíga náà kúrò ní Ísírẹ́lì; síbẹ̀síbẹ̀ ọkàn Ásà wà ní pípé ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.

18. Ó sì mú àwọn ohun mímọ́ náà ti baba rẹ̀ àti àwọn ohun mímọ́ ti òun tìkára rẹ̀ tirẹ̀ wá sínú ilé Ọlọ́run, wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò náà.

19. Kò sí ogun mọ́ títí fún ọdún márùndínlógójì ti ìjọba Ásà.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 15