Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 15:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Ásáríyà ọmọ Ódédì.

2. Ó jáde lọ bá Ásà, ó sì wí fún un pé, “Tẹ́tí si mi Ásà, àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì. Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà pẹ̀lú rẹ̀. Ti ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ní ẹ̀bá rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ silẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

3. Fún ọjọ́ pípẹ́ ni Ísírẹ́lì ti wà láì sin Ọlọ́run òtitọ́, àti láìní àlùfáà ti ń kọ́ ni, àti láì ní òfin.

4. Ṣùgbọ́n nínú ìpọ́njú wọn, wọ́n yí padà si Olúwa Ọlọ́run Isírẹ̀lì, wọ́n sì wa kiri. Wọ́n sì ri i ní ẹ̀gbẹ́ wọn.

5. Ní ọjọ́ wọ̀nnì ó léwu kí ènìyàn máa rìn ìrìnàjò kiri, nítorí tí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà wà nínú làálàá ńlá

6. Orílẹ̀-èdè kan ń run èkejì àti ìlu kan sí òmíràn nítorí Olúwa ń yọ wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìpọ́njú.

7. Ṣùgbọ́n fun ìwọ, jẹ́ alágbára, kí ó má sì se sú ọ. Nítorí tí a ó fi èrè sí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ”

8. Nígbà tí Ásà gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Ásáríyà ọmọ Ódédì wòlíì, ó mú àyà rẹ̀ le. Ó gbé àwọn òrìsà ìkóríra kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti kúrò nínú àwọn ìlú tí ó ti fi agbára mú ní ori òkè Éfúráímù. Ó tún pẹpẹ Olúwa ṣe tí ó wà ní iwájú Pórífíkò ti ilé Olúwa

9. Nígbà naà, ó pe gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ àti àwọn ènìyàn láti Éfúráímù, Mánásè àti Síméónì tí ó ti ṣe àtìpó ní àárin wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Ísírẹ́lì nigbà tí wọ́n rí i wí pé Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 15