Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 13:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa; òun ni olórí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò dún dídùn ogun sí i yín. Ẹyin ọkùnrin Ísírẹ́lì, Ẹ má ṣe dojú ìjà kọ Olúwa Ọlọ́run baba a yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege.”

13. Nísinsìn yìí, Jéróbóámù ti rán àwọn ọ̀wọ́ ogun lọ yíká láti jagun ẹ̀yìn. Kí ó lè jẹ́ pé, tí òun bá wà ní wájú Júdà, bíba ní bùba á wà ní ẹ̀yìn wọn.

14. Nígbà tí Júdà sì bojúwo ẹ̀yìn, sì kíyèsi i, ogun ń bẹ níwáju àti lẹ́yìn, wọn sì ké pe Olúwa, àwọn àlùfáà sì fun ìpè

15. Olúkúlùkù, ọkùnrin Júdà sì hó: ó sì ṣe, bí àwọn ọkùnrin Júdà sì ti hó, ni Ọlọ́run kọlu Jéróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì níwájú Ábíjà àti Júdà.

16. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sálọ kúrò níwájú Júdà, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́.

17. Ábíjà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdàmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Ísírẹ́lì.

18. Báyìí ni a rẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní àkókò náà, àwọn ọmọ Júdà sì borí nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn.

19. Ábíjà sì lépa Jéróbóámù, ó sì gba ìlú lọ́wọ́ rẹ̀, Bétílì pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Jeṣánà pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Éufúráímù pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀.

20. Bẹ́ẹ̀ ní Jéróbóámù kò sì tún ní agbára mọ́ ní ọjọ́ Ábíjà. Olúwa sì lù ú ó sì kú.

21. Ábíjà sì di alágbára, ó sì gbé obìnrin mẹ́talá ní ìyàwó, ó sì bi ọmọkùnrin méjìlélógún, àti ọmọbìnrin mẹ́rìndinlógún.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 13