Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 11:10-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ṣórà, Áíjálónì, àti Hébírónì. Wọ̀nyí ni àwọn ìlu ìdábòbò ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì.

11. Ó sì mú àwọn ìlú olódi lágbára, ó sì fi àwọn balógun sínú wọn àti àkójọ oúnjẹ, àti òróró àti ọtí wáìnì.

12. Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi àsà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì lábẹ́ rẹ̀.

13. Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì, láti gbogbo ẹ̀yà wọn jákè jádò Ísírẹ́lì wà ní ẹ̀bá rẹ̀.

14. Àwọn ará Léfì fi ìgbéríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù nítorí Jéróbóamù àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Olúwa.

15. Ó sì yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn Ibi gíga àti fún ewúrẹ́ àti àwọn òrìṣà ti a gbẹ́ tí o ti ṣẹ̀.

16. Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tẹ̀lé àwọn ará Léfì lọ sí Jérúsálẹ́mù láti lọ rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run bàbá a wọn.

17. Ó fún ìjọba Júdà ní agbára, ó sì ti Réhóbóámù ọmọ Sólómónì lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dáfídì àti Sólómónì ní àkókò yí.

18. Réhóbóámù fẹ́ Máhálátì tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ọmọkùnrin Dáfídì Jérímótì àti ti Ábíháílì, ọmọbìnrin ọmọkùnrin ti Jésè Élíábì.

19. Ó bí àwọn ọmọ fún un: Jéúṣì, Ṣémáríà àti Ṣáhámì.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 11