Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 11:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Réhóbóámù dé Jérúsálẹ́mù, ó kó ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ ológun, láti bá Ísírẹ́lì jà kí ó lè mú ìjọba naà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Réhóbóámù.

2. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí wá sí ọ̀dọ̀ Ṣémáíà ènìyàn Ọlọ́run:

3. “Wí fún Rehóbóámù ọmọ Sólómónì ọba Júdà, sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì,

4. ‘Èyí ní ohun tí Olúwa wí. Ẹ má ṣe gòkè lọ lati lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jéróbóámù.

5. Réhóbóámù ń gbe ní Jérúsálẹ́mù ó sì kọ́ àwọn ìlú fún ààbò ní Júdà.

6. Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Étamì, Tẹ́kóà,

7. Beti-Súrì, sókò, Ádúlámù

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 11