Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 9:20-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Fún ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sọnù fún ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, má ṣe dàamú nípa wọ́n: a ti rí wọn. Sí ta ni gbogbo ìfẹ́ Ísírẹ́lì wà? Bí kì í ṣe sí ìwọ àti sí gbogbo ilé baba à rẹ.”

21. Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Ṣùgbọ́n èmi kì í há à ṣe ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Kékeré nínú ẹ̀yá Ísírẹ́lì: Ìdílé mi kò há rẹ̀yìn jùlọ nínú gbogbo ẹyà Bẹ́ńjámínì? Èésì ti ṣe tí ìwọ sọ̀rọ̀ yìí sí mi?”

22. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú Ṣọ́ọ̀lù pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngàn, ó sì mú wọn jókòó sí iwájú àwọn tí a pè—tí wọn tó ọgbọ̀n.

23. Sámúẹ́lì sọ fún aláṣè pé, “Mú ìpín ẹran tí mo fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ pé kí o yà sọ́tọ̀.”

24. Alásè náà sì gbé ẹṣẹ̀ náà pẹ̀lú ohun tí ó wà lórí i rẹ̀, ó sì gbé e ṣíwájú Ṣọ́ọ̀lù. Sámúẹ́lì wí pé, “Èyí ni ohun tí a fi pamọ́ fún ọ. Jẹ, nítorí a yà á sọ́tọ̀ fún ọ, fún ìdí yìí, láti ìgbà tí mo ti wí pé, ‘Mo ní àlejò tí a pè.’ ” Ṣọ́ọ̀lù sì jẹun pẹ̀lú Sámúẹ́lì ní ọjọ́ náà.

25. Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti sọ̀kalẹ̀ láti ibí gíga náà wá sí inú ìlú, Sámúẹ́lì sì bá Ṣọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lórí òrùlé ilé e rẹ̀.

26. Wọ́n sì dìde ní àfẹ̀mọ́jú, ó pe Ṣọ́ọ̀lù sórí òrùlé pé, “Múra, èmi yóò rán ọ lọ.” Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù múra tán òun àti Sámúẹ́lì jọ jáde lọ síta.

27. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìpẹ̀kun ìlú náà, Sámúẹ́lì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Sọ fún ìránṣẹ́ náà kí ó máa lọ ṣáájú u wa,” ìránṣẹ́ náà sì ṣe bẹ̀ẹ́, “ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó dúró díẹ̀, kí èmi kí ó lè sọ ọrọ̀ láti ọ̀dọ Ọlọ́run fún ọ.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 9