Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 5:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dágónì sì wá, ó ṣubú ó dojú bolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.

5. Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà Dágónì tàbí àwọn mìíràn tí ó wo inú tẹ́ḿpìlì Dágónì ní Ásídódù fi ń tẹ orí ìloro ẹnu ọ̀nà.

6. Ọwọ́ Olúwa wúwo lára àwọn ènìyàn Ásídódù àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú àrùn oníkókó.

7. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ásídódù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Olúwa ti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára Dágónì ọlọ́run wá.”

8. Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Fílístínì jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn Ísírẹ́lì?”Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn Ísírẹ́lì lọ sí Gátì.” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

9. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ Olúwa sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn oníkókó.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 5