Nígbà tí àwọn ará Ásídódù jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dágónì ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa, wọ́n sì gbé Dágónì, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀.