Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 5:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Fílístínì ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ, wọ́n gbé e láti Ebenésérì sí Ásídódù.

2. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí náà lọ sí Tẹ́ḿpìlì Dágónì, wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ Dágónì.

3. Nígbà tí àwọn ará Ásídódù jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dágónì ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa, wọ́n sì gbé Dágónì, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀.

4. Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dágónì sì wá, ó ṣubú ó dojú bolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.

5. Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà Dágónì tàbí àwọn mìíràn tí ó wo inú tẹ́ḿpìlì Dágónì ní Ásídódù fi ń tẹ orí ìloro ẹnu ọ̀nà.

6. Ọwọ́ Olúwa wúwo lára àwọn ènìyàn Ásídódù àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú àrùn oníkókó.

7. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ásídódù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Olúwa ti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára Dágónì ọlọ́run wá.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 5