Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sámúẹ́lì ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú Olúwa ní abẹ́ Élì. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ Olúwa ṣọ̀wọ́n: kò sì sí ìran púpọ̀.

2. Ní alẹ́ ọjọ́ kan Élì ẹni tí ojú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí di aláìlágbára, tí kò sì ríran dáadáa, ó dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀ bi ti àtẹ̀yìn wá.

3. Nígbà tí iná kò tí ì kú Sámúẹ́lì dùbúlẹ̀ nínú tẹ́ḿpìlì Olúwa, níbi tí àpótí Olúwa gbé wà.

4. Nígbà náà ni Olúwa pe Sámúẹ́lì.Sámúẹ́lì sì dáhùn “Èmi nìyí”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 3