Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 28:11-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Obìnrin náà sì bi í pé, “Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ?”Òun sì wí pé, “Mú Sámúẹ́lì gòkè wá fún mi.”

12. Nígbà tí obìnrin náà sì rí Sámúẹ́lì, ó kígbe lóhùn rara: obìnrin náà sì bá Ṣọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ pè, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ? Nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù ni ìwọ jẹ́.”

13. Ọba sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù; kín ni ìwọ rí?”Obìnrin náà sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èmi rí ẹ̀mí kan tí ó ti ilẹ̀ wá.”

14. Ó sì bi í pé, “Báwo ni ó ti rí i sí.”Ó sì wí pé, “Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ; ó sì fi agbádá bora.”Ṣọ́ọ̀lù sì mọ̀ pé, Sámúẹ́lì ni; ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀.

15. Sámúẹ́lì sì i wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?”Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Fílístínì ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.”

16. Sámúẹ́lì sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀.

17. Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dáfídì.

18. Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Ámálékì nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí.

19. Olúwa yóò sì fi Ísírẹ́lì pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́: ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi: Olúwa yóò sì fi ogun Ísírẹ́lì lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́.”

20. Lojúkan náà ni Ṣọ́ọ̀lù ṣubú lulẹ̀ gbalaja ní bí ó ṣe gùn tó, ẹ̀rù sì bà á gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì; agbára kò sí fún un; nítorí pé kò jẹun ní ọjọ́ náà t'ọ̀sán t'òru.

21. Obìnrin náà sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá, ó sì rí i pé ó wà nínú ìbànújẹ́ púpọ̀, ó sì wí fún un pé, “Wò ó, ìránṣẹ́bìnrin rẹ́ ti gbọ́ ohun rẹ̀, èmi sì ti fi ẹ̀mi mi sí ọwọ́ mi, èmi sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ti ìwọ sọ fún mi.

22. Ǹjẹ́, nísinsìnyìí èmi bẹ̀ ọ́, gbọ́ ohùn ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi yóò sì fi oúnjẹ díẹ̀ ṣíwájú rẹ̀; sì jẹun, ìwọ yóò sì lágbára, nígbà tí ìwọ bá ń lọ lọ́nà.”

23. Ṣùgbọ́n ó kọ̀, ó sì wí pé, “Èmi kì yóò jẹun.”Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rọ̀ ọ́. Ó sì dide kúrò ni ilẹ̀, ó sì jókòó lorí àkéte.

24. Obìnrin náà sì ni ẹgbọrọ màlúù kan ti ó sańra ni ilé, ó sì yára, ó pa á, ó sì mú ìyẹ̀fún, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà àìwú.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 28