Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 28:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, àwọn Fílístínì sì kó àwọn ogun wọn jọ, láti bá Ísírẹ́lì jà. Ákíṣì sì wí fún Dáfídì pé, “Mọ dájúdájú pé, ìwọ yóò bá mi jáde lọ sí ibi ìjà, ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ.”

2. Dáfídì sì wí fún Ákíṣì, pé, “Nítòótọ́ ìwọ ó sì mọ ohun tí ìránṣẹ rẹ lè ṣe.”Ákíṣì sì wí fún Dáfídì pé, “Nítorí náà ni èmi ó ṣe fi ìwọ ṣe olùṣọ́ orí mi ni gbogbo ọjọ́.”

3. Sámúẹ́lì sì ti kú, gbogbo Ísírẹ́lì sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rámà ní ìlú rẹ̀. Ṣọ́ọ̀lù sì ti mú àwọn abókúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà.

4. Àwọn Fílístínì sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣúnémù: Ṣọ́ọ̀lù sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gílíbóà.

5. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì rí ogun àwọn Fílístínì náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi.

6. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Úrímù tàbí nípa àwọn wòlíì.

7. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mi abókúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Ẹ́ńdórì tí ó ní ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 28