Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 19:6-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣọ́ọ̀lù fetísí Jónátanì, ó sì búra báyìí, “Níwọ̀n ìgbà tí Olúwa bá ti ń bẹ láàyè, a kì yóò pa Dáfídì.”

7. Nítorí náà Jónátanì pe Dáfídì, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un. Ó sì mú un wá fún Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì sì wà lọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.

8. Lẹ́ẹ̀kàn an sí i ogun tún wá, Dáfídì sì jáde lọ, ó sì bá àwọn ara Fílístínì jà. Ó sì pa wọn pẹ̀lú agbára, wọ́n sì sálọ níwájú u rẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí orí Ṣọ́ọ̀lù bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ rẹ̀. Bí Dáfídì sì ti fọn ohun èlò orin olókùn,

10. Ṣọ́ọ̀lù sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dáfídì yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ṣọ́ọ̀lù ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dáfídì sì fi ara pamọ́ dáradára.

11. Ṣọ́ọ̀lù rán ènìyàn sí ilé Dáfídì láti sọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n Míkálì, ìyàwó Dáfídì kìlọ̀ fún un pé, “Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí ì rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a ó ò pa ọ́.”

12. Nígbà náà Míkálì sì gbé Dáfídì sọ̀kalẹ̀ ó sì fi aṣọ bò ó.

13. Míkálì gbé ère ó sì tẹ́ e lórí ibùsùn, ó sì fi irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀.

14. Nígbà ti Ṣọ́ọ̀lù rán ènìyàn láti lọ fi agbára mú Dáfídì, Míkálì wí pé, “Ó rẹ̀ ẹ́.”

15. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù rán ọkùnrin náà padà láti lọ wo Dáfídì ó sì sọ fún wọn pé, “Mú wa fún mi láti orí ibùsùn rẹ̀ kí èmi kí ó le pa á.”

16. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ère ni ó bá lórí ibùsùn àti irun ewúrẹ́ ní orí ère náà.

17. Ṣọ́ọ̀lù wí fún Míkálì pé, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí báyìí tí o sì jẹ́ kí ọ̀ta mi sálọ tí ó sì bọ́?”Míkálì sọ fún un pé, “Ó wí fún mi, jẹ́ kí èmi ó lọ. Èéṣe tí èmi yóò fi pa ọ́?”

18. Nígbà tí Dáfídì ti sá lọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà ó sì sọ gbogbo ohun tí Ṣọ́ọ̀lù ti ṣe fún un. Òun àti Sámúẹ́lì lọ sí Náíótì láti dúró níbẹ̀.

19. Ọ̀rọ̀ sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá pé, “Dáfídì wà ní Náíótì ní Rámà,”

20. ó sì rán àwọn ènìyàn láti fi agbára mú u wá ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì tí ń ṣọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Sámúẹ́lì dúró níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí, ẹ̀mí Ọlọ́run sì wá sórí àwọn arákùnrin Ṣọ́ọ̀lù àwọn náà sì ń ṣọtẹ́lẹ̀.

21. Wọ́n sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, ó sì rán ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn lọ àwọn náà sì ń ṣọtẹ́lẹ̀. Ṣọ́ọ̀lù tún rán oníṣẹ́ lọ ní ìgbà kẹta, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣọtẹ́lẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 19