Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 19:3-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà. Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ.”

4. Jónátanì sọ̀rọ̀ rere nípa Dáfídì fún Ṣọ́ọ̀lù baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀.

5. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pa Fílístínì. Olúwa ṣẹ́ ogun ńlá fún gbogbo Ísírẹ́lì, ìwọ rí i inú rẹ dùn. Èéṣe nígbà náà tí ìwọ yóò fi ṣe ohun búburú sí ọkùnrin aláìṣẹ̀ láìnídìí?”

6. Ṣọ́ọ̀lù fetísí Jónátanì, ó sì búra báyìí, “Níwọ̀n ìgbà tí Olúwa bá ti ń bẹ láàyè, a kì yóò pa Dáfídì.”

7. Nítorí náà Jónátanì pe Dáfídì, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un. Ó sì mú un wá fún Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì sì wà lọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.

8. Lẹ́ẹ̀kàn an sí i ogun tún wá, Dáfídì sì jáde lọ, ó sì bá àwọn ara Fílístínì jà. Ó sì pa wọn pẹ̀lú agbára, wọ́n sì sálọ níwájú u rẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí orí Ṣọ́ọ̀lù bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ rẹ̀. Bí Dáfídì sì ti fọn ohun èlò orin olókùn,

10. Ṣọ́ọ̀lù sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dáfídì yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ṣọ́ọ̀lù ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dáfídì sì fi ara pamọ́ dáradára.

11. Ṣọ́ọ̀lù rán ènìyàn sí ilé Dáfídì láti sọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n Míkálì, ìyàwó Dáfídì kìlọ̀ fún un pé, “Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí ì rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a ó ò pa ọ́.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 19