Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 19:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nígbẹ̀yìn, òun fúnra rẹ̀ sì lọ sí Rámà ó sì dé ibi àmù ńlá kan ní Ṣékù. Ó sì béèrè, “Níbo ni Sámúẹ́lì àti Dáfídì wà?”Wọ́n wí pé, “Wọ́n wà ní ìrékọjá ní Náíótì ní Rámà.”

23. Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí Náíótì ni Rámà. Ṣùgbọ́n, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e lórí ó sì ń lọ lọ́nà, ó sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Náíótì.

24. Ó sì bọ́ aṣọ rẹ̀, òun pẹ̀lú sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ níwájú Sámúẹ́lì. Ó sì dùbúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà àti ní òru. Ìdí nìyìí tí àwọn ènìyàn fi wí pé, “Ṣé Ṣọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì ni?”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 19