Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 17:16-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Fún ogójì ọjọ́, Fílístínì wá ṣíwájú ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ wọ́n sì fi ara wọn hàn.

17. Nísinsìn yìí Jésè wí fún ọmọ rẹ̀ Dáfídì pé, “Mú ìwọ̀n éfà àti àgbàdo yíyan àti ìṣù àkàrà mẹ́wàá lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ kí o sì ṣéré lọ sí ibùdó o wọn.

18. Kí o sì mú wàrà mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún adarí ogun ti wọn. Wo bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe wà kí o sì padà wá fún mi ní àmìn ìdánilójú láti ọ̀dọ̀ wọn.

19. Wọ́n wà pẹ̀lú u Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ní àfonífojì Élà, wọ́n bá àwọn Fílístínì jà.”

20. Ní àárọ̀ kùtùkùtù Dáfídì fi agbo ẹran rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùtọ́jú, ó di ẹrù, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n gẹ́gẹ́ bí Jésè ti sọ fún un. Ó dé ibùdó bí àwọn ọmọ ogun ti ń lọ láti dúró ní ipò wọn ní ojú ogun, wọ́n hó ìhó ogun.

21. Ísírẹ́lì àti Fílístínì lọ sí ojú ìjà wọ́n da ojú ìjà kọ ara wọn.

22. Dáfídì sì kó ẹrù rẹ̀ ti àwọn olùtọ́jú ohun èlò, ó sì sá lọ sí ojú ogun ó sì kí àwọn ẹ̀gbọ́n ọn rẹ̀.

23. Bí ó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, Gòláyátì akíkanjú Fílístínì tí ó wá láti Gátì yọra sí iwájú ní ojú ogun, ó sì kígbe fún ìpèníjà, Dáfídì sì gbọ́.

24. Nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì rí ọkùnrin náà, gbogbo wọn sì sá fún un ní ìbẹ̀rù-bojo.

25. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wí pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ríi bí ọkùnrin yìí ṣe ń jáde wá? Ó jáde wá láti pe Ísírẹ́lì níjà. Ọba yóò fún ọkùnrin tí ó bá pa á ní ọrọ̀ púpọ̀. Yóò tún fi ọmọ rẹ̀ obìnrin fún un ní ìyàwó, yóò sì sọ ilé e baba rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú sísan owó orí ní Ísírẹ́lì.”

26. Dáfídì béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Kí ni a ó ò ṣe fún ọkùnrin náà tí ó bá pa Fílístínì yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Ísírẹ́lì? Ta ni aláìkọlà Fílístínì tí ó jẹ́ wí pé yóò máa gan ogun Ọlọ́run alààyè?”

27. Wọ́n tún sọ fún un ohun tí wọ́n ti ń sọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí wọn yóò ṣe fún ọkùnrin tí ó bá pa á.”

28. Nígbà tí Élíábù ẹ̀gbọ́n Dáfídì gbọ́ nígbà tí ó ń bá ọkùnrin yìí sọ̀rọ̀, ó bínú sí i, ó sì wí pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ fi sọ̀kalẹ̀ wá síbí? Àti pé ta ni ìwọ fi àwọn àgùntàn kékeré tó kù ṣọ́ ní ihà? Èmi mọ ìgbéraga rẹ, àti búburú ọkàn rẹ: ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá nìkan láti wòran ogun.”

29. Dáfídì wí pé, “Kí ni mo ṣe nísinsìn yìí? Ǹjẹ́ mo lè sọ̀rọ̀ bí?”

30. Ó sì yípadà sí ẹlòmíràn, ó sì ń sọ̀rọ̀ kán náà, ọkùnrin náà sì dáhùn bí ti ẹni ìṣáájú.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 17