Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 17:12-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nísinsìn yìí Dáfídì jẹ́ ọmọ ará Éfúrátà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jésè, tí ó wá látí Bétílẹ́hẹ́mù ní Júdà, Jésè ní ọmọ mẹ́jọ, ní àsìkò Sáulù ó ti darúgbó ẹni ọdún púpọ̀.

13. Àwọn ọmọ Jésè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ti dàgbà bá Ṣọ́ọ̀lù lọ sí ojú ogun: Èyí àkọ́bí ni Élíábù: Èyí èkejì ni Ábínádábù, èyí ẹ̀kẹta sì ní Ṣámínà.

14. Dáfídì ni ó kéré jù nínú wọn. Àwọn àgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì tẹ̀lé Ṣọ́ọ̀lù,

15. Ṣùgbọ́n Dáfídì padà lẹ́yìn Ṣọ́ọ̀lù, láti máa tọ́jú àgùntàn baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

16. Fún ogójì ọjọ́, Fílístínì wá ṣíwájú ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ wọ́n sì fi ara wọn hàn.

17. Nísinsìn yìí Jésè wí fún ọmọ rẹ̀ Dáfídì pé, “Mú ìwọ̀n éfà àti àgbàdo yíyan àti ìṣù àkàrà mẹ́wàá lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ kí o sì ṣéré lọ sí ibùdó o wọn.

18. Kí o sì mú wàrà mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún adarí ogun ti wọn. Wo bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe wà kí o sì padà wá fún mi ní àmìn ìdánilójú láti ọ̀dọ̀ wọn.

19. Wọ́n wà pẹ̀lú u Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ní àfonífojì Élà, wọ́n bá àwọn Fílístínì jà.”

20. Ní àárọ̀ kùtùkùtù Dáfídì fi agbo ẹran rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùtọ́jú, ó di ẹrù, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n gẹ́gẹ́ bí Jésè ti sọ fún un. Ó dé ibùdó bí àwọn ọmọ ogun ti ń lọ láti dúró ní ipò wọn ní ojú ogun, wọ́n hó ìhó ogun.

21. Ísírẹ́lì àti Fílístínì lọ sí ojú ìjà wọ́n da ojú ìjà kọ ara wọn.

22. Dáfídì sì kó ẹrù rẹ̀ ti àwọn olùtọ́jú ohun èlò, ó sì sá lọ sí ojú ogun ó sì kí àwọn ẹ̀gbọ́n ọn rẹ̀.

23. Bí ó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, Gòláyátì akíkanjú Fílístínì tí ó wá láti Gátì yọra sí iwájú ní ojú ogun, ó sì kígbe fún ìpèníjà, Dáfídì sì gbọ́.

24. Nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì rí ọkùnrin náà, gbogbo wọn sì sá fún un ní ìbẹ̀rù-bojo.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 17