Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 17:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Fílístínì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ fún ogun ní Síkọ̀ ti Júdà. Wọ́n pàgọ́ sí Efesidámímù, láàárin Síkọ̀ àti Ásékà,

2. Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ́n kò ara wọ́n jọ pọ̀, wọ́n sì pàgọ́ ní àfonífojì ní Élà wọ́n sì gbé ogun wọn sókè ní ọ̀nà láti pàdé àwọn Fílístínì.

3. Àwọn Fílístínì sì wà ní orí òkè kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì wà ní orí òkè mìíràn, àfonífojì sì wà láàrin wọn.

4. Ọ̀gágun tí a ń pè ní Gòláyátì, tí ó jẹ́ ará Gátì, ó wá láti ibùdó Fílístínì. Ó ga ní ìwọ̀n mítà mẹ́ta.

5. Ó ní àsíborí idẹ ní orí rẹ̀, ó sì wọ ẹ̀wù tí a fi idẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọ̀n ẹ̀wù náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣékélì idẹ, (5,000) (kìlógírámù mẹ́tadínlọ́gọ́ta).

6. Òun sì wọ ìhámọ́ra idẹ sí ẹsẹ̀ rẹ̀ àti àpáta idẹ kan láàrin ẹ̀yìn rẹ̀.

7. Ọ̀pá rẹ̀ rí bí apása ìhunṣọ, orí ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì wọn (600) kilogírámù méje irin, ẹni tí ó ru asà ogun rẹ̀ lọ ṣáájú u rẹ̀.

8. Gòláyátì dìde, ó sì kígbe sí ogun Ísírẹ́lì pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi jáde wá, tí ẹ ṣe tò fún ogun? Ṣé èmi kì í ṣe Fílístínì ni, àbí ẹ̀yin kì í ṣe ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù? Yan ọkùnrin kan kí o sì jẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi.

9. Tí òhun bá sì le jà tí ó sì pa mí, àwa yóò di ẹrú u yín, ṣùgbọ́n tí èmi bá lè ṣẹ́gun rẹ̀ tí mo sì pa á, ẹ̀yin yóò di ẹrú u wa, ẹ̀yin yóò sì máa sìn wá.”

10. Nígbà náà Fílístínì náà wí pé, “Èmi fi ìjà lọ ogun Ísírẹ́lì ní òní! Ẹ mú ọkùnrin kan wá kí ẹ sì jẹ́ kí a bá ara wa jà.”

11. Nígbà tí Sáulù àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Fílístínì, ìdààmú bá wọn

12. Nísinsìn yìí Dáfídì jẹ́ ọmọ ará Éfúrátà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jésè, tí ó wá látí Bétílẹ́hẹ́mù ní Júdà, Jésè ní ọmọ mẹ́jọ, ní àsìkò Sáulù ó ti darúgbó ẹni ọdún púpọ̀.

13. Àwọn ọmọ Jésè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ti dàgbà bá Ṣọ́ọ̀lù lọ sí ojú ogun: Èyí àkọ́bí ni Élíábù: Èyí èkejì ni Ábínádábù, èyí ẹ̀kẹta sì ní Ṣámínà.

14. Dáfídì ni ó kéré jù nínú wọn. Àwọn àgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì tẹ̀lé Ṣọ́ọ̀lù,

15. Ṣùgbọ́n Dáfídì padà lẹ́yìn Ṣọ́ọ̀lù, láti máa tọ́jú àgùntàn baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

16. Fún ogójì ọjọ́, Fílístínì wá ṣíwájú ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ wọ́n sì fi ara wọn hàn.

17. Nísinsìn yìí Jésè wí fún ọmọ rẹ̀ Dáfídì pé, “Mú ìwọ̀n éfà àti àgbàdo yíyan àti ìṣù àkàrà mẹ́wàá lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ kí o sì ṣéré lọ sí ibùdó o wọn.

18. Kí o sì mú wàrà mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún adarí ogun ti wọn. Wo bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe wà kí o sì padà wá fún mi ní àmìn ìdánilójú láti ọ̀dọ̀ wọn.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 17