Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 16:9-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Jésè sì jẹ́ kí Sámà rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì, ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí náà.”

10. Jésè jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ méje rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì sọ fún un pé, “Olúwa kò yan àwọn wọ̀nyí.”

11. Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jésè pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?”Jésè dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.”Sámúẹ́lì sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.”

12. Ó sì ráńṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi.Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Dìde kí o sì fi òroró yàn án, òun ni ẹni náà.”

13. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mi mímọ́ Olúwa wá sí orí Dáfídì nínú agbára. Sámúẹ́lì sì lọ sí Rámà.

14. Nísinsìn yìí, ẹ̀mi Olúwa ti kúrò lára Ṣọ́ọ̀lù, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa sì ń yọ ọ́ lẹ́nu.

15. Àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu.

16. Jẹ́ kí Olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.”

17. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi.”

18. Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jésè ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. Olúwa sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.”

19. Ṣọ́ọ̀lù sì rán oníṣẹ́ sí Jésè wí pé, “Rán Dáfídì ọmọ rẹ sí mi, ẹni tí ó ń ṣọ́ àgùntàn.”

20. Jésè sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti a di ẹrù lé àti ìgò ọtí wáìnì àti ọmọ ewúrẹ́; ó sì rán wọn nípa ọwọ́ ọ Dáfídì ọmọ rẹ̀ sí Ṣọ́ọ̀lù.

21. Dáfídì sì tọ Ṣọ́ọ̀lù lọ, ó sì dúró níwájú rẹ̀: òun sì fẹ́ ẹ gidigidi, Dáfídì sì wá di ẹni tí ń ru ìhámọ́ra rẹ̀.

22. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù ránṣẹ́ sí Jésè, pé, “Jẹ́ kí Dáfídì dúró níwájú mi, nítorí tí ó wù mí.”

23. Ó sì ṣe, nígbà tí ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá bá dé sí Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì a sì fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lára dùùrù: a sì san fún Ṣọ́ọ̀lù, ara rẹ̀ a sì dá; ẹ̀mi búburú náà a sì fi sílẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 16