Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 16:2-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Sùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé; “Báwo ni èmi yóò ṣe lọ? Bí Ṣọ́ọ̀lù bá gbọ́ nípa rẹ̀, yóò pa mi.” Olúwa wí pé, “Mú abo ẹgbọ̀rọ̀ màlúù kan pẹ̀lú rẹ, kí o sì wí pé, ‘Èmi wá láti wá rúbọ sí Olúwa.’

3. Pe Jésè wá sí ibi ìrúbọ náà, Èmi yóò sì fi ohun tí ìwọ yóò ṣe hàn ọ́. Ìwọ yóò fi òróró yàn fún mi, ẹni tí èmi bá fi hàn ọ́.”

4. Sámúẹ́lì ṣe ohun tí Olúwa sọ. Nígbà tí ó dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àyà gbogbo àgbààgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé, “Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá?”

5. Sámúẹ́lì sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rúbọ sí Olúwa. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rúbọ pẹ̀lú ù mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jésè sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà.

6. Nígbà tí wọ́n dé, Sámúẹ́lì rí Élíábù, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró Olúwa dúró níbí níwájú Olúwa.

7. Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn.”

8. Nígbà náà ni Jésè pe Ábínádábù, ó sì jẹ́ kí ó rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí.”

9. Jésè sì jẹ́ kí Sámà rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì, ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí náà.”

10. Jésè jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ méje rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì sọ fún un pé, “Olúwa kò yan àwọn wọ̀nyí.”

11. Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jésè pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?”Jésè dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.”Sámúẹ́lì sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.”

12. Ó sì ráńṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi.Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Dìde kí o sì fi òroró yàn án, òun ni ẹni náà.”

13. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mi mímọ́ Olúwa wá sí orí Dáfídì nínú agbára. Sámúẹ́lì sì lọ sí Rámà.

14. Nísinsìn yìí, ẹ̀mi Olúwa ti kúrò lára Ṣọ́ọ̀lù, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa sì ń yọ ọ́ lẹ́nu.

15. Àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu.

16. Jẹ́ kí Olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.”

17. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi.”

18. Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jésè ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. Olúwa sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.”

19. Ṣọ́ọ̀lù sì rán oníṣẹ́ sí Jésè wí pé, “Rán Dáfídì ọmọ rẹ sí mi, ẹni tí ó ń ṣọ́ àgùntàn.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 16