Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 15:29-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Ẹni tí ó ń ṣe ògo Ísírẹ́lì, kì í purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í yí ọkàn rẹ̀ padà; nítorí kì í ṣe ènìyàn tí yóò yí ọkàn rẹ̀ padà.”

30. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Èmi ti ṣẹ̀, ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbààgbà ènìyàn mi, àti níwájú u Ísírẹ́lì, yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè tẹríba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ.”

31. Bẹ́ẹ̀ ni Sámúẹ́lì sì yípadà pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì sin Olúwa.

32. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí pé, “Mú Ágágì ọba àwọn ará Ámálékì wá fún mi.”Ágágì sì tọ̀ ọ́ wá ní ìgboyà pẹ̀lú èrò pé, “Nítòótọ́ ìkorò ikú ti kọjá.”

33. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé,“Bí idà rẹ ti sọ àwọn obìnrin di aláìní ọmọbẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ yóò sì di aláìní ọmọ láàárin obìnrin.”Sámúẹ́lì sì pa Ágágì níwájú Olúwa ni Gílígálì.

34. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì lọ sí Rámà, Ṣọ́ọ̀lù sì gòkè lọ sí ilé e rẹ̀ ní Gíbéà tí Ṣọ́ọ̀lù.

35. Sámúẹ́lì kò sì padà wá mọ́ láti wo Ṣọ́ọ̀lù títí ó fi di ọjọ́ ikú u rẹ̀, ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì káànú fún Ṣọ́ọ̀lù. Ó sì dun Olúwa pé ó fi Ṣọ́ọ̀lù jọba lórí Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 15