Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 15:22-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì dáhùn pé,“Ǹjẹ́ Olúwa ní inú dídùn sí ọrẹ sísun àti ẹbọju kí a ṣe ohun tí Olúwa wí?Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ,ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.

23. Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ,àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà.Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa,Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”

24. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún Sámúẹ́lì pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin Olúwa àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́.

25. Mo bẹ̀ ọ́ nísinsìn yìí, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn, kí ó sì yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè sin Olúwa.”

26. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí fún un pé, “Èmi kò ní bá ọ padà. Ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa sílẹ̀, Olúwa sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì!”

27. Bí Sámúẹ́lì sì ti fẹ́ yípadà láti lọ, Ṣọ́ọ̀lù sì di ẹ̀wù ìlekè rẹ̀ mú, ó sì fàya;

28. Sámúẹ́lì sì wí fún un pé, “Olúwa ti fa ìjọba Ísírẹ́lì ya kúrò lọ́wọ́ ọ̀ rẹ lónìí, ó sì ti fi fún aládùúgbò rẹ kan tí ó sàn jù ọ́ lọ.

29. Ẹni tí ó ń ṣe ògo Ísírẹ́lì, kì í purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í yí ọkàn rẹ̀ padà; nítorí kì í ṣe ènìyàn tí yóò yí ọkàn rẹ̀ padà.”

30. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Èmi ti ṣẹ̀, ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbààgbà ènìyàn mi, àti níwájú u Ísírẹ́lì, yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè tẹríba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ.”

31. Bẹ́ẹ̀ ni Sámúẹ́lì sì yípadà pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì sin Olúwa.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 15