Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 14:3-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. lára wọn ni Áhíjà, tí ó wọ Éfódù. Òun ni ọmọ arákùnrin Íkábódù Áhítúbì, ọmọ Fínéhásì, ọmọ Élì, àlùfáà Olúwa ní Ṣílò kò sí ẹni tí ó mọ̀ pé Jónátanì ti lọ.

4. Ní ọ̀nà tí Jónátanì ti ń fẹ́ láti kọjá dé ìlú olódi àwọn Fílístínì, ní bèbè òkúta mímú kan wá, orúkọ èkíní sì ń jẹ́ Bóṣéṣì, orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Sénè.

5. Bèbè òkúta kan dúró sí àríwá ní ìhà Míkímásì, èkejì sì wà ní gúsù ní ìhà Gíbéà.

6. Jónátanì sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlu olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá Olúwa yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di Olúwa lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípaṣẹ̀ púpọ̀ tàbí nípaṣẹ̀ díẹ̀.”

7. Ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì wí pé, “Ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ, tẹ̀ṣíwájú; Èmi wà pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ.”

8. Jónátanì sì wí pé, “Wá nígbà náà, àwa yóò rékọjá sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin wọ̀nyí, kí a sì jẹ́ kí wọ́n rí wa.

9. Bí wọ́n bá sọ fún wa pé, ‘Ẹ dúró títí àwa yóò fi tọ̀ yín wá,’ àwa yóò dúró síbi tí a wà, àwa kì yóò sì gòkè tọ̀ wọ́n lọ.

10. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wí pé, ‘Ẹ gòkè tọ̀ wá wá,’ àwa yóò gòkè lọ, nítorí èyí ni yóò jẹ́ àmì fún wa pé Olúwa ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́.”

11. Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Fílístínì. Àwọn Fílístínì sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Hébérù ń fà jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 14