Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 14:27-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ṣùgbọ́n Jónátanì kò gbọ́ pé baba rẹ̀ ti fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ orí ọ̀pá tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bọ afárá oyin náà, ó sì fi sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dán.

28. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun sọ fún un pé, “Baba rẹ fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ogun wí pé, ‘Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ ní òní!’ Ìdí nìyìí tí àárẹ̀ fi mú àwọn ènìyàn.”

29. Jónátánì sì wí pé, “Baba mi ti mú ìdàámú bá ìlú, wò ó bí ojú mi ti dán nígbà tí mo fi ẹnu kan oyin yìí.

30. Báwo ni kò bá ti dára tó bí àwọn ènìyàn bá ti jẹ nínú ìkógun àwọn ọ̀ta wọn lónìí, pípa àwọn Fílístínì ìbá ti pọ̀ tó?”

31. Ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pa nínú àwọn Fílístínì láti Míkímásì dé Áíjálónì, ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà.

32. Wọ́n sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùntàn. Màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n sórí ilẹ̀, wọ́n sì jẹ wọ́n papọ̀ tẹ̀jẹ́tẹ̀jẹ̀.

33. Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́sẹ̀ sí Olúwa nípa jíjẹ ẹrán tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára.”Ó sì wí pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá síbi nísinsìn yìí.”

34. Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí Olúwa, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun tẹ̀jẹ̀.’ ”Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.

35. Nígbà náà Ṣọ́ọ̀lù kọ́ pẹpẹ kan fún Olúwa; èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe èyí.

36. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ tọ Fílístínì lọ ní òru, kí a bá wọn jà títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, kí a má sìṣe dá ẹnìkankan sí nínú wọn.”Wọ́n sì wí pé, “Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀.”Ṣùgbọ́n àlùfáà wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọ́run níhìn ín.”

37. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, “Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Fílístínì lọ bí? Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ bí?” Ṣùgbọ́n Olúwa kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.

38. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ wá síhìn ín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olórí ogun, kí a ṣe ìwádìí irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti ṣẹ̀ lónìí.

39. Bí Olúwa tí ó gba Ísírẹ́lì là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jónátanì ọmọ mi, ó ní láti kú.” Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan.

40. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ẹ lọ sí apá kan; èmi àti Jónátanì ọmọ mi yóò lọ sí apá kan.”Gbogbo àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú rẹ.”

41. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì pé, “Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́.” A sì mú Jónátanì àti Ṣọ́ọ̀lù nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege.

42. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ dìbò láàárin èmi àti Jónátanì ọmọ mi.” Ìbò náà sì mú Jónátanì.

43. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Jónátanì pé, “Sọ nǹkan tí ìwọ ṣe fún mi.”Jónátanì sì sọ fún un pé, “Mo kàn fi orí ọ̀pá mi tọ́ oyin díẹ̀ wò. Nísinsìn yìí ṣé mo ní láti kú?”

44. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí mi, bí ìwọ kò bá kú.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 14